Native Bible

John 4:33 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń bi ara wọn lérè wí pé, “Ẹnìkan mú oúnjẹ fún un wá láti jẹ bí?”

John 4:33 in English

John 4:33 · Berean Standard Bible

So the disciples asked one another, “Could someone have brought Him food?”

Context

31Láàrín èyí, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń rọ̀ ọ́ wí pé, “Rabbi, jẹun.” 32Ṣùgbọ́n ó wí fún wọn pé, “Èmi ní oúnjẹ láti jẹ, tí ẹ̀yin kò mọ̀.” 33Nítorí náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ń bi ara wọn lérè wí pé, “Ẹnìkan mú oúnjẹ fún un wá láti jẹ bí?” 34Jesu wí fún wọn pé, “Oúnjẹ mi ni láti ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi, àti láti parí iṣẹ́ rẹ̀. 35Ẹ̀yin kò ha wí pé, ‘Ó ku oṣù mẹ́rin, ìkórè yóò sì dé?’ wò ó, mo wí fún un yín, Ẹ ṣí ojú yín sókè, kí ẹ sì wo oko; nítorí tí wọn ti pọ́n fún ìkórè.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.