Native Bible

John 4:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Obìnrin náà wí fún un pé, mo mọ̀ pé, “Messia ń bọ̀ wá, tí a ń pè ní Kristi, nígbà tí Òun bá dé, yóò sọ ohun gbogbo fún wa.”

John 4:25 in English

John 4:25 · Berean Standard Bible

The woman said, “I know that Messiah” (called Christ) “is coming. When He comes, He will explain everything to us.”

Context

23Ṣùgbọ́n àkókò ń bọ̀, ó sì dé tán nísinsin yìí, nígbà tí àwọn olùsìn tòótọ́ yóò máa sin Baba ní ẹ̀mí àti ní òtítọ́, nítorí irú wọn ni Baba ń wá kí ó máa sin òun. 24Ẹ̀mí ni Ọlọ́run: àwọn ẹni tí ń sìn ín kò lè ṣe aláìsìn ín ní Ẹ̀mí àti ní òtítọ́.” 25Obìnrin náà wí fún un pé, mo mọ̀ pé, “Messia ń bọ̀ wá, tí a ń pè ní Kristi, nígbà tí Òun bá dé, yóò sọ ohun gbogbo fún wa.” 26Jesu sọ ọ́ di mí mọ̀ fún un pé, “Èmi ẹni tí ń bá ọ sọ̀rọ̀ yìí ni Òun.” 27Lákokò yí ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ dé, ẹnu sì yà wọ́n pé ó ń bá obìnrin sọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan tí ó wí pé, “Kí ni ìwọ ń wá?” tàbí “Èéṣe tí ìwọ fi ń bá a sọ̀rọ̀?”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.