Johanu 20:28
John 20:28 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Tomasi dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Olúwa mi àti Ọlọ́run mi!”
John 20:28 in English
John 20:28 · Berean Standard Bible
Thomas replied, “My Lord and my God!”
Context
26Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́jọ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sì tún wà nínú ilé, àti Tomasi pẹ̀lú wọn: nígbà tí a sì ti ti ìlẹ̀kùn, Jesu dé, ó sì dúró láàrín, ó wí pé, “Àlàáfíà fún yín.” 27Nígbà náà ni ó wí fún Tomasi pé, “Mú ìka rẹ wá níhìn-ín yìí, kí o sì wo ọwọ́ mi; sì mú ọwọ́ rẹ wá níhìn-ín, kí o sì fi sí ìhà mi: kí ìwọ má ṣe jẹ́ aláìgbàgbọ́ mọ́, ṣùgbọ́n jẹ́ onígbàgbọ́.” 28Tomasi dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Olúwa mi àti Ọlọ́run mi!” 29Jesu wí fún un pé, “Nítorí tí ìwọ rí mi ni ìwọ ṣe gbàgbọ́, alábùkún fún ni àwọn tí kò rí mi, tí wọ́n sì gbàgbọ́!” 30Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àmì mìíràn ni Jesu ṣe níwájú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, tí a kò kọ sínú ìwé yìí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.