Native Bible

John 19:33 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jesu, tí wọ́n sì rí i pé ó ti kú, wọn kò ṣẹ́ egungun itan rẹ̀,

John 19:33 in English

John 19:33 · Berean Standard Bible

But when they came to Jesus and saw that He was already dead, they did not break His legs.

Context

31Nítorí ó jẹ́ ọjọ́ ìpalẹ̀mọ́, kí òkú wọn má ba à wà lórí àgbélébùú ní ọjọ́ ìsinmi (nítorí ọjọ́ ńlá ni ọjọ́ ìsinmi náà), nítorí náà, àwọn Júù bẹ Pilatu pé kí a ṣẹ́ egungun itan wọn, kí a sì gbé wọn kúrò. 32Nítorí náà, àwọn ọmọ-ogun wá, wọ́n sì ṣẹ́ egungun itan ti èkínní, àti ti èkejì, tí a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀. 33Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ Jesu, tí wọ́n sì rí i pé ó ti kú, wọn kò ṣẹ́ egungun itan rẹ̀, 34ṣùgbọ́n ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ogun náà fi ọ̀kọ̀ gún un lẹ́gbẹ̀ẹ́, lójúkan náà, ẹ̀jẹ̀ àti omi sì tú jáde. 35Ẹni tí ó rí sì jẹ́rìí, òtítọ́ sì ni ẹ̀rí rẹ̀, ó sì mọ̀ pé òtítọ́ ni òun sọ, kí ẹ̀yin ba à lè gbàgbọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.