Native Bible

John 19:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ́n sì wí pé, “Kábíyèsí, ọba àwọn Júù!” Wọ́n sì fi ọwọ́ wọn gbá a ní ojú.

John 19:3 in English

John 19:3 · Berean Standard Bible

And they went up to Him again and again, saying, “Hail, King of the Jews!” and slapping Him in the face.

Context

1Nítorí náà ni Pilatu mú Jesu, ó sì nà án. 2Àwọn ọmọ-ogun sì hun adé ẹ̀gún, wọ́n sì fi dé e ní orí, wọ́n sì fi aṣọ ìgúnwà elése àlùkò wọ̀ ọ́. 3Wọ́n sì wí pé, “Kábíyèsí, ọba àwọn Júù!” Wọ́n sì fi ọwọ́ wọn gbá a ní ojú. 4Pilatu sì tún jáde, ó sì wí fún wọn pé, “Wò ó, mo mú u jáde tọ̀ yín wá, kí ẹ̀yin kí ó lè mọ̀ pé, èmi kò rí ẹ̀ṣẹ̀ kan lọ́wọ́ rẹ̀.” 5Nítorí náà Jesu jáde wá, ti òun ti adé ẹ̀gún àti aṣọ elése àlùkò. Pilatu sì wí fún wọn pé, “Ẹ wò ọkùnrin náà!”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.