Johanu 18:24
John 18:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí Annasi rán an lọ ní dídè sọ́dọ̀ Kaiafa olórí àlùfáà.
John 18:24 in English
John 18:24 · Berean Standard Bible
Then Annas sent Him, still bound, to Caiaphas the high priest.
Context
22Bí ó sì ti wí èyí tan, ọ̀kan nínú àwọn aláṣẹ tí ó dúró tì í fi ọwọ́ rẹ̀ lu Jesu, pé, “Alábojútó àlùfáà ni ìwọ ń dá lóhùn bẹ́ẹ̀?” 23Jesu dá a lóhùn pé, “Bí mo bá sọ̀rọ̀ búburú, jẹ́rìí sí búburú náà, ṣùgbọ́n bí rere bá ni, èéṣe tí ìwọ fi ń lù mí?” 24Nítorí Annasi rán an lọ ní dídè sọ́dọ̀ Kaiafa olórí àlùfáà. 25Ṣùgbọ́n Simoni Peteru dúró, ó sì ń yáná. Nígbà náà ni wọ́n wí fún un pé, “Ìwọ pẹ̀lú ha jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀?”
Ó sì sẹ́, wí pé, “Èmi kọ́.” 26Ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà, tí ó jẹ́ ìbátan ẹni tí Peteru gé etí rẹ̀ sọnù, wí pé, “Èmi ko ha rí ọ pẹ̀lú rẹ̀ ní àgbàlá?”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.