Native Bible

John 16:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ọjọ́ náà, ẹ̀yin ó béèrè ní orúkọ mi, èmi kò sì wí fún yín pé, èmi ó béèrè lọ́wọ́ Baba fún yín.

John 16:26 in English

John 16:26 · Berean Standard Bible

In that day you will ask in My name. I am not saying that I will ask the Father on your behalf.

Context

24Títí di ìsinsin yìí ẹ kò tí ì béèrè ohunkóhun ní orúkọ mi, ẹ béèrè, ẹ ó sì rí gbà, kí ayọ̀ yín kí ó lè kún. 25“Nǹkan wọ̀nyí ni mo fi òwe sọ fún yín: ṣùgbọ́n àkókò dé, nígbà tí èmi kì yóò fi òwe bá yín sọ̀rọ̀ mọ́, ṣùgbọ́n èmi ó sọ nípa ti Baba fún yín gbangba. 26Ní ọjọ́ náà, ẹ̀yin ó béèrè ní orúkọ mi, èmi kò sì wí fún yín pé, èmi ó béèrè lọ́wọ́ Baba fún yín. 27Nítorí tí Baba tìkára rẹ̀ fẹ́ràn yín, nítorí tí ẹ̀yin ti fẹ́ràn mi, ẹ sì ti gbàgbọ́ pé, lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni èmi ti jáde wá. 28Mo ti ọ̀dọ̀ Baba jáde wá, mo sì wá sí ayé, àti nísinsin yìí mo fi ayé sílẹ̀, mo sì lọ sọ́dọ̀ Baba.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.