Johanu 16:24
John 16:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Títí di ìsinsin yìí ẹ kò tí ì béèrè ohunkóhun ní orúkọ mi, ẹ béèrè, ẹ ó sì rí gbà, kí ayọ̀ yín kí ó lè kún.
John 16:24 in English
John 16:24 · Berean Standard Bible
Until now you have not asked for anything in My name. Ask and you will receive, so that your joy may be complete.
Context
22Nítorí náà ẹ̀yin ní ìbànújẹ́ nísinsin yìí, ṣùgbọ́n èmi ó tún rí yín, ọkàn yín yóò sì yọ̀, kò sì sí ẹni tí yóò gba ayọ̀ yín lọ́wọ́ yín. 23Àti ní ọjọ́ náà ẹ̀yin kì ó bi mí lérè ohunkóhun. Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ohunkóhun tí ẹ̀yin bá béèrè lọ́wọ́ Baba ní orúkọ mi, òhun ó fi fún yín. 24Títí di ìsinsin yìí ẹ kò tí ì béèrè ohunkóhun ní orúkọ mi, ẹ béèrè, ẹ ó sì rí gbà, kí ayọ̀ yín kí ó lè kún. 25“Nǹkan wọ̀nyí ni mo fi òwe sọ fún yín: ṣùgbọ́n àkókò dé, nígbà tí èmi kì yóò fi òwe bá yín sọ̀rọ̀ mọ́, ṣùgbọ́n èmi ó sọ nípa ti Baba fún yín gbangba. 26Ní ọjọ́ náà, ẹ̀yin ó béèrè ní orúkọ mi, èmi kò sì wí fún yín pé, èmi ó béèrè lọ́wọ́ Baba fún yín.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.