Native Bible

John 15:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Gẹ́gẹ́ bí Baba ti fẹ́ mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi sì fẹ́ yín, ẹ dúró nínú ìfẹ́ rẹ̀.

John 15:9 in English

John 15:9 · Berean Standard Bible

As the Father has loved Me, so have I loved you. Remain in My love.

Context

7Bí ẹ̀yin bá ń gbé inú mi, tí ọ̀rọ̀ mi bá sì gbé inú yín, ẹ ó béèrè ohunkóhun tí ẹ bá fẹ́, a ó sì ṣe é fún yín. 8Nínú èyí ní a yìn Baba mi lógo pé, kí ẹ̀yin kí ó máa so èso púpọ̀; ẹ̀yin ó sì jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi. 9“Gẹ́gẹ́ bí Baba ti fẹ́ mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi sì fẹ́ yín, ẹ dúró nínú ìfẹ́ rẹ̀. 10Bí ẹ̀yin bá pa òfin mi mọ́, ẹ ó dúró nínú ìfẹ́ mi; gẹ́gẹ́ bí èmi ti pa òfin Baba mi mọ́, tí mo sì dúró nínú ìfẹ́ rẹ̀. 11Nǹkan wọ̀nyí ni mo ti sọ fún yín, kí ayọ̀ mi kí ó lè wà nínú yín, àti kí ayọ̀ yín kí ó lè kún.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.