Johanu 15:8
John 15:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nínú èyí ní a yìn Baba mi lógo pé, kí ẹ̀yin kí ó máa so èso púpọ̀; ẹ̀yin ó sì jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi.
John 15:8 in English
John 15:8 · Berean Standard Bible
This is to My Father’s glory, that you bear much fruit, proving yourselves to be My disciples.
Context
6Bí ẹnìkan kò bá gbé inú mi, a gbé e sọnù gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka, a sì gbẹ; wọn a sì kó wọn jọ, wọn a sì sọ wọ́n sínú iná, wọn a sì jóná. 7Bí ẹ̀yin bá ń gbé inú mi, tí ọ̀rọ̀ mi bá sì gbé inú yín, ẹ ó béèrè ohunkóhun tí ẹ bá fẹ́, a ó sì ṣe é fún yín. 8Nínú èyí ní a yìn Baba mi lógo pé, kí ẹ̀yin kí ó máa so èso púpọ̀; ẹ̀yin ó sì jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi. 9“Gẹ́gẹ́ bí Baba ti fẹ́ mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi sì fẹ́ yín, ẹ dúró nínú ìfẹ́ rẹ̀. 10Bí ẹ̀yin bá pa òfin mi mọ́, ẹ ó dúró nínú ìfẹ́ mi; gẹ́gẹ́ bí èmi ti pa òfin Baba mi mọ́, tí mo sì dúró nínú ìfẹ́ rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.