Native Bible

John 14:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Filipi wí fún un pé, “Olúwa, fi Baba náà hàn wá, yóò sì tó fún wa.”

John 14:8 in English

John 14:8 · Berean Standard Bible

Philip said to Him, “Lord, show us the Father, and that will be enough for us.”

Context

6Jesu dá wọn lóhùn pé, “Èmi ni ọ̀nà, òtítọ́ àti ìyè, kò sí ẹnikẹ́ni tí ó lè wá sọ́dọ̀ Baba, bí kò ṣe nípasẹ̀ mi. 7Ìbá ṣe pé ẹ̀yin ti mọ̀ mí, ẹ̀yin ìbá ti mọ Baba mi pẹ̀lú, láti ìsinsin yìí lọ ẹ̀yin mọ̀ ọ́n, ẹ sì ti rí i.” 8Filipi wí fún un pé, “Olúwa, fi Baba náà hàn wá, yóò sì tó fún wa.” 9Jesu wí fún un pé, “Bí àkókò tí mo bá yín gbé ti tó yìí, ìwọ, kò sì tí ì mọ̀ mí síbẹ̀ Filipi? Ẹni tí ó bá ti rí mi, ó ti rí Baba. Ìwọ ha ti ṣe wí pé, ‘Fi Baba hàn wá!’ 10Ìwọ kò ha gbàgbọ́ pé, èmi wà nínú Baba, àti pé Baba wà nínú mi? Ọ̀rọ̀ tí èmi ń sọ fún yín, èmi kò dá a sọ; ṣùgbọ́n Baba ti ó wà nínú mi, òun ní ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.