Johanu 13:3
John 13:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
tí Jesu sì ti mọ̀ pé Baba ti fi ohun gbogbo lé òun lọ́wọ́, àti pé lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni òun ti wá, òun sì ń lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run;
John 13:3 in English
John 13:3 · Berean Standard Bible
Jesus knew that the Father had delivered all things into His hands, and that He had come from God and was returning to God.
Context
1Ǹjẹ́ kí àjọ ìrékọjá tó dé, nígbà tí Jesu mọ̀ pé, wákàtí rẹ̀ dé tan, tí òun ó ti ayé yìí kúrò lọ sọ́dọ̀ Baba, fífẹ́ tí ó fẹ́ àwọn tirẹ̀ tí ó wà ní ayé, ó fẹ́ wọn títí dé òpin. 2Bí wọ́n sì ti ń jẹ oúnjẹ alẹ́, tí èṣù ti fi í sí ọkàn Judasi Iskariotu ọmọ Simoni láti fi í hàn; 3tí Jesu sì ti mọ̀ pé Baba ti fi ohun gbogbo lé òun lọ́wọ́, àti pé lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni òun ti wá, òun sì ń lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run; 4Ó dìde ní ìdí oúnjẹ alẹ́, ó sì fi agbádá rẹ̀ lélẹ̀ ní apá kan; nígbà tí ó sì mú aṣọ ìnura, ó di ara rẹ̀ ní àmùrè. 5Lẹ́yìn náà, ó bu omi sínú àwokòtò kan, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í máa wẹ ẹsẹ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ó sì ń fi aṣọ ìnura tí ó fi di àmùrè nù wọ́n.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.