Native Bible

John 13:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí wọ́n sì ti ń jẹ oúnjẹ alẹ́, tí èṣù ti fi í sí ọkàn Judasi Iskariotu ọmọ Simoni láti fi í hàn;

John 13:2 in English

John 13:2 · Berean Standard Bible

The evening meal was underway, and the devil had already put into the heart of Judas, the son of Simon Iscariot, to betray Jesus.

Context

1Ǹjẹ́ kí àjọ ìrékọjá tó dé, nígbà tí Jesu mọ̀ pé, wákàtí rẹ̀ dé tan, tí òun ó ti ayé yìí kúrò lọ sọ́dọ̀ Baba, fífẹ́ tí ó fẹ́ àwọn tirẹ̀ tí ó wà ní ayé, ó fẹ́ wọn títí dé òpin. 2Bí wọ́n sì ti ń jẹ oúnjẹ alẹ́, tí èṣù ti fi í sí ọkàn Judasi Iskariotu ọmọ Simoni láti fi í hàn; 3tí Jesu sì ti mọ̀ pé Baba ti fi ohun gbogbo lé òun lọ́wọ́, àti pé lọ́dọ̀ Ọlọ́run ni òun ti wá, òun sì ń lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run; 4Ó dìde ní ìdí oúnjẹ alẹ́, ó sì fi agbádá rẹ̀ lélẹ̀ ní apá kan; nígbà tí ó sì mú aṣọ ìnura, ó di ara rẹ̀ ní àmùrè.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.