Johanu 13:27
John 13:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní kété tí Judasi gba àkàrà náà ni Satani wọ inú rẹ̀ lọ. Nítorí náà Jesu wí fún un pé, “Ohun tí ìwọ ń ṣe nì, yára ṣe é kánkán.”
John 13:27 in English
John 13:27 · Berean Standard Bible
And when Judas had taken the morsel, Satan entered into him. Then Jesus said to Judas, “What you are about to do, do quickly.”
Context
25Ẹni tí ó ń rọ̀gún ní àyà Jesu wí fún un pé, “Olúwa, ta ni í ṣe?” 26Nítorí náà Jesu dáhùn pé, “Òun náà ni, ẹni tí mo bá fi àkàrà fún nígbà tí mo bá fi run àwo.” Nígbà tí ó sì fi run ún tan, ó fi fún Judasi Iskariotu ọmọ Simoni. 27Ní kété tí Judasi gba àkàrà náà ni Satani wọ inú rẹ̀ lọ.
Nítorí náà Jesu wí fún un pé, “Ohun tí ìwọ ń ṣe nì, yára ṣe é kánkán.” 28Kò sì sí ẹnìkan níbi tábìlì tí ó mọ ìdí tí ó ṣe sọ èyí fún un. 29Nítorí àwọn mìíràn nínú wọn rò pé, nítorí Judasi ni ó ni àpò, ni Jesu fi wí fún un pé, ra nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí a kò le ṣe aláìní fún àjọ náà; tàbí kí ó lè fi nǹkan fún àwọn tálákà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.