Native Bible

John 13:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Kì í ṣe ti gbogbo yín ni mo ń sọ, èmi mọ àwọn tí mo yàn, ṣùgbọ́n kí Ìwé Mímọ́ bá à lè ṣẹ, ‘Ẹni tí ń bá mi jẹun pọ̀ sì gbé gìgísẹ̀ rẹ̀ sí mi.’

John 13:18 in English

John 13:18 · Berean Standard Bible

I am not speaking about all of you; I know whom I have chosen. But this is to fulfill the Scripture: ‘The one who shares My bread has lifted up his heel against Me.’*

Context

16Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ọmọ ọ̀dọ̀ kò tóbi ju ọ̀gá rẹ̀ lọ, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí a rán kò tóbi ju ẹni tí ó rán an lọ. 17Bí ẹ̀yin bá mọ nǹkan wọ̀nyí, alábùkún fún ni yín, bí ẹ̀yin bá ń ṣe wọ́n! 18“Kì í ṣe ti gbogbo yín ni mo ń sọ, èmi mọ àwọn tí mo yàn, ṣùgbọ́n kí Ìwé Mímọ́ bá à lè ṣẹ, ‘Ẹni tí ń bá mi jẹun pọ̀ sì gbé gìgísẹ̀ rẹ̀ sí mi.’ 19“Láti ìsinsin yìí lọ ni mo wí fún un yín kí ó tó dé, pé nígbà tí ó bá dé, kí ẹ̀yin lè gbàgbọ́ pé èmi ni. 20Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, ẹni tí ó bá gba ẹnikẹ́ni tí mo rán, ó gbà mí; ẹni tí ó bá sì gbà mí, ó gba ẹni tí ó rán mi.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.