Native Bible

John 13:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ọmọ ọ̀dọ̀ kò tóbi ju ọ̀gá rẹ̀ lọ, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí a rán kò tóbi ju ẹni tí ó rán an lọ.

John 13:16 in English

John 13:16 · Berean Standard Bible

Truly, truly, I tell you, no servant is greater than his master,* nor is a messenger greater than the one who sent him.

Context

14Ǹjẹ́ bí èmi tí í ṣe Olúwa àti olùkọ́ yín bá wẹ ẹsẹ̀ yín, ó tọ́ kí ẹ̀yin pẹ̀lú sì máa wẹ ẹsẹ̀ ara yín. 15Nítorí mo fi àpẹẹrẹ fún yín, kí ẹ̀yin lè máa ṣe gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe sí yín. 16Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ọmọ ọ̀dọ̀ kò tóbi ju ọ̀gá rẹ̀ lọ, bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí a rán kò tóbi ju ẹni tí ó rán an lọ. 17Bí ẹ̀yin bá mọ nǹkan wọ̀nyí, alábùkún fún ni yín, bí ẹ̀yin bá ń ṣe wọ́n! 18“Kì í ṣe ti gbogbo yín ni mo ń sọ, èmi mọ àwọn tí mo yàn, ṣùgbọ́n kí Ìwé Mímọ́ bá à lè ṣẹ, ‘Ẹni tí ń bá mi jẹun pọ̀ sì gbé gìgísẹ̀ rẹ̀ sí mi.’

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.