Native Bible

John 12:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí Jesu sì rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan, ó gùn ún; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé pé,

John 12:14 in English

John 12:14 · Berean Standard Bible

Finding a young donkey, Jesus sat on it, as it is written:

Context

12Ní ọjọ́ kejì nígbà tí ọ̀pọ̀ ènìyàn tí ó wá sí àjọ gbọ́ pé, Jesu ń bọ̀ wá sí Jerusalẹmu. 13Wọ́n mú imọ̀ ọ̀pẹ, wọ́n sì jáde lọ pàdé rẹ̀, wọ́n sì ń kígbe pé, “Hosana!” “Olùbùkún ni ẹni tí ń bọ̀ wá ní orúkọ Olúwa!” “Olùbùkún ni ọba Israẹli!” 14Nígbà tí Jesu sì rí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan, ó gùn ún; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé pé, 15“Má bẹ̀rù, ọmọbìnrin Sioni; wò ó, ọba rẹ ń bọ̀ wá, o jókòó lórí ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.” 16Nǹkan wọ̀nyí kò tètè yé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, ṣùgbọ́n nígbà tí a ṣe Jesu lógo, nígbà náà ni wọ́n rántí pé, a kọ̀wé nǹkan wọ̀nyí nípa rẹ̀ sí i.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.