Johanu 11:55
John 11:55 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àjọ ìrékọjá àwọn Júù sì súnmọ́ etílé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti ìgbèríko sì gòkè lọ sí Jerusalẹmu ṣáájú ìrékọjá, láti ya ara wọn sí mímọ́.
John 11:55 in English
John 11:55 · Berean Standard Bible
Now the Jewish Passover was near, and many people went up from the country to Jerusalem to purify themselves before the Passover.
Context
53Nítorí náà, láti ọjọ́ náà lọ ni wọ́n ti jọ gbìmọ̀ pọ̀ láti pa á. 54Nítorí náà Jesu kò rìn ní gbangba láàrín àwọn Júù mọ́; ṣùgbọ́n ó ti ibẹ̀ lọ sí ìgbèríko kan tí ó súnmọ́ aginjù, sí ìlú ńlá kan tí a ń pè ní Efraimu, níbẹ̀ ni ó sì wà pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. 55Àjọ ìrékọjá àwọn Júù sì súnmọ́ etílé, ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti ìgbèríko sì gòkè lọ sí Jerusalẹmu ṣáájú ìrékọjá, láti ya ara wọn sí mímọ́. 56Nígbà náà ni wọ́n ń wá Jesu, wọ́n sì ń bá ara wọn sọ̀, bí wọ́n ti dúró ní tẹmpili, wí pé, “Kín ni ẹyin ti rò ó sí pé kì yóò wá sí àjọ?” 57Ǹjẹ́ àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisi ti pàṣẹ pé bí ẹnìkan bá mọ ibi tí ó gbé wà, kí ó fi í hàn, kí wọn ba à lè mú un.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.