Native Bible

John 10:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Olè àti ọlọ́ṣà ni gbogbo àwọn tí ó ti wà ṣáájú mi, ṣùgbọ́n àwọn àgùntàn kò gbọ́ tiwọn.

John 10:8 in English

John 10:8 · Berean Standard Bible

All who came before Me * were thieves and robbers, but the sheep did not listen to them.

Context

6Òwe yìí ni Jesu pa fún wọn, ṣùgbọ́n òye ohun tí nǹkan wọ̀nyí tí ó ń sọ fún wọn kò yé wọn. 7Nítorí náà Jesu tún wí fún wọn pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Èmi ni ìlẹ̀kùn àwọn àgùntàn. 8Olè àti ọlọ́ṣà ni gbogbo àwọn tí ó ti wà ṣáájú mi, ṣùgbọ́n àwọn àgùntàn kò gbọ́ tiwọn. 9Èmi ni ìlẹ̀kùn, bí ẹnìkan bá bá ọ̀dọ̀ mi wọlé, òun ni a ó gbàlà, yóò wọlé, yóò sì jáde, yóò sì rí koríko. 10Olè kì í wá bí kò ṣe láti jalè, láti pa, àti láti parun; èmi wá kí wọn lè ní ìyè, àní kí wọn lè ní i lọ́pọ̀lọ́pọ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.