Native Bible

John 10:35 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Bí ó bá pè wọ́n ní ‘ọlọ́run,’ àwọn ẹni tí a fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún, a kò sì lè ba ìwé mímọ́ jẹ́.

John 10:35 in English

John 10:35 · Berean Standard Bible

If he called them gods to whom the word of God came—and the Scripture cannot be broken—

Context

33Àwọn Júù sì dá a lóhùn pé, “Àwa kò sọ ọ́ lókùúta nítorí iṣẹ́ rere, ṣùgbọ́n nítorí ọ̀rọ̀-òdì, àti nítorí ìwọ tí í ṣe ènìyàn ń fi ara rẹ pe Ọlọ́run.” 34Jesu dá wọn lóhùn pé, “A kò ha tí kọ ọ́ nínú òfin yín pé, ‘Mo ti wí pé, Ọlọ́run ni ẹ̀yin jẹ́’? 35Bí ó bá pè wọ́n ní ‘ọlọ́run,’ àwọn ẹni tí a fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún, a kò sì lè ba ìwé mímọ́ jẹ́. 36Kín ni ẹyin ha ń wí ní ti ẹni tí Baba yà sọ́tọ̀, tí ó sì rán sí ayé kín lo de ti ẹ fi ẹ̀sùn kàn mi pé mò ń sọ̀rọ̀-òdì nítorí pé mo sọ pé, ‘Èmi ni Ọmọ Ọlọ́run.’ 37Bí èmi kò bá ṣe iṣẹ́ Baba mi, ẹ má ṣe gbà mí gbọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.