Johanu 10:33
John 10:33 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Àwọn Júù sì dá a lóhùn pé, “Àwa kò sọ ọ́ lókùúta nítorí iṣẹ́ rere, ṣùgbọ́n nítorí ọ̀rọ̀-òdì, àti nítorí ìwọ tí í ṣe ènìyàn ń fi ara rẹ pe Ọlọ́run.”
John 10:33 in English
John 10:33 · Berean Standard Bible
“We are not stoning You for any good work,” said the Jews, “but for blasphemy, because You, who are a man, declare Yourself to be God.”
Context
31Àwọn Júù sì tún mú òkúta, láti sọ lù ú. 32Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ rere ni mo fihàn yín láti ọ̀dọ̀ Baba mi wá, nítorí èwo nínú iṣẹ́ wọ̀nyí ni ẹ̀yin ṣe sọ mí ní òkúta?” 33Àwọn Júù sì dá a lóhùn pé, “Àwa kò sọ ọ́ lókùúta nítorí iṣẹ́ rere, ṣùgbọ́n nítorí ọ̀rọ̀-òdì, àti nítorí ìwọ tí í ṣe ènìyàn ń fi ara rẹ pe Ọlọ́run.” 34Jesu dá wọn lóhùn pé, “A kò ha tí kọ ọ́ nínú òfin yín pé, ‘Mo ti wí pé, Ọlọ́run ni ẹ̀yin jẹ́’? 35Bí ó bá pè wọ́n ní ‘ọlọ́run,’ àwọn ẹni tí a fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún, a kò sì lè ba ìwé mímọ́ jẹ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.