Johanu 1:35
John 1:35 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní ọjọ́ kejì, Johanu dúró pẹ̀lú méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.
John 1:35 in English
John 1:35 · Berean Standard Bible
The next day John was there again with two of his disciples.
Context
33Èmi kì bá tí mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe pé ẹni tí ó rán mi láti fi omi bamitiisi sọ fún mi pé, ‘Ọkùnrin tí ìwọ rí tí Ẹ̀mí sọ̀kalẹ̀ tí ó bà lé lórí ni ẹni tí yóò fi Ẹ̀mí Mímọ́ bamitiisi.’ 34Èmi ti rí i, mo sì jẹ́rìí pé, èyí ni Ọmọ Ọlọ́run.” 35Ní ọjọ́ kejì, Johanu dúró pẹ̀lú méjì nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. 36Nígbà tí ó sì rí Jesu bí ó ti ń kọjá lọ, ó wí pé, “Wò ó Ọ̀dọ́-àgùntàn Ọlọ́run!” 37Nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì náà sì gbọ́ ohun tí ó wí yìí, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sì í tọ Jesu lẹ́yìn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.