Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Èmi yóò mú òpin bá ìró ayọ̀ àti ìdùnnú àti ohùn àwọn tọkọtaya ní àwọn ìlú Juda àti ní ìgboro Jerusalẹmu, nítorí tí ilẹ̀ náà yóò di ahoro.

Jeremiah 7:34 in English

Jeremiah 7:34 · Berean Standard Bible

I will remove from the cities of Judah and the streets of Jerusalem the sounds of joy and gladness and the voices of the bride and bridegroom, for the land will become a wasteland.”

Context

32Nítorí náà kíyèsára ọjọ́ ń bọ̀, ni Olúwa wí, nígbà tí àwọn ènìyàn kò ní pè é ní Tafeti tàbí àfonífojì ti Beni-Hinnomu; ṣùgbọ́n yóò ma jẹ àfonífojì ìparun, nítorí wọn yóò sin òkú sí Tofeti títí kò fi ní sí ààyè mọ́. 33Nígbà náà ni òkú àwọn ènìyàn wọ̀nyí yóò di oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹranko ilẹ̀, kò sì ní sí ẹnìkan tí yóò dẹ́rùbà wọ́n. 34Èmi yóò mú òpin bá ìró ayọ̀ àti ìdùnnú àti ohùn àwọn tọkọtaya ní àwọn ìlú Juda àti ní ìgboro Jerusalẹmu, nítorí tí ilẹ̀ náà yóò di ahoro.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.