Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí náà kíyèsára ọjọ́ ń bọ̀, ni Olúwa wí, nígbà tí àwọn ènìyàn kò ní pè é ní Tafeti tàbí àfonífojì ti Beni-Hinnomu; ṣùgbọ́n yóò ma jẹ àfonífojì ìparun, nítorí wọn yóò sin òkú sí Tofeti títí kò fi ní sí ààyè mọ́.

Jeremiah 7:32 in English

Jeremiah 7:32 · Berean Standard Bible

So behold, the days are coming, declares the LORD, when this place will no longer be called Topheth and the Valley of Hinnom, but the Valley of Slaughter. For they will bury the dead in Topheth until there is no more room.

Context

30“ ‘Àwọn ènìyàn Juda ti ṣe búburú lójú mi, ni Olúwa wí. Wọ́n ti to àwọn ère ìríra wọn jọ sí ilé tí a fi orúkọ mi pè wọ́n sì ti sọ ọ́ di àìmọ́. 31Wọ́n ti kọ́ àwọn ibi gíga ti Tofeti ní àfonífojì Beni-Hinnomu láti sun àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn nínú iná èyí tí èmi kò pàṣẹ tí kò sì wá sí ọkàn mi. 32Nítorí náà kíyèsára ọjọ́ ń bọ̀, ni Olúwa wí, nígbà tí àwọn ènìyàn kò ní pè é ní Tafeti tàbí àfonífojì ti Beni-Hinnomu; ṣùgbọ́n yóò ma jẹ àfonífojì ìparun, nítorí wọn yóò sin òkú sí Tofeti títí kò fi ní sí ààyè mọ́. 33Nígbà náà ni òkú àwọn ènìyàn wọ̀nyí yóò di oúnjẹ fún àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run àti ẹranko ilẹ̀, kò sì ní sí ẹnìkan tí yóò dẹ́rùbà wọ́n. 34Èmi yóò mú òpin bá ìró ayọ̀ àti ìdùnnú àti ohùn àwọn tọkọtaya ní àwọn ìlú Juda àti ní ìgboro Jerusalẹmu, nítorí tí ilẹ̀ náà yóò di ahoro.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.