Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Dúró ní ẹnu-ọ̀nà ilé Olúwa kí o sì kéde ọ̀rọ̀ yí: “ ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀yin ará Juda tí ń gba ọ̀nà yí wọlé láti wá sin Olúwa.

Jeremiah 7:2 in English

Jeremiah 7:2 · Berean Standard Bible

“Stand in the gate of the house of the LORD and proclaim this message: Hear the word of the LORD, all you people of Judah who enter through these gates to worship the LORD.

Context

1Èyí ni ọ̀rọ̀ tó tọ Jeremiah wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa. 2“Dúró ní ẹnu-ọ̀nà ilé Olúwa kí o sì kéde ọ̀rọ̀ yí: “ ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa gbogbo ẹ̀yin ará Juda tí ń gba ọ̀nà yí wọlé láti wá sin Olúwa. 3Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí: Tún àwọn ọ̀nà yín ṣe, èmi yóò sì jẹ́ kí ẹ gbé ilẹ̀ yìí. 4Má ṣe gba ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn gbọ́ kí ẹ sì wí pé, “Èyí ni tẹmpili Olúwa ilé tẹmpili Olúwa, ilé tẹmpili Olúwa!”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.