Jeremiah 7:17
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣé ìwọ kò rí ohun tí wọ́n ń ṣe ní àwọn ìlú Juda àti ní òpópó Jerusalẹmu?
Jeremiah 7:17 in English
Jeremiah 7:17 · Berean Standard Bible
Do you not see what they are doing in the cities of Judah and in the streets of Jerusalem?
Context
15Èmi yóò tú kúrò ní iwájú mi gẹ́gẹ́ bí mo ti ṣe sí àwọn arákùnrin yín, àwọn ará Efraimu.’ 16“Nítorí náà má ṣe gbàdúrà fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí tàbí kí o bẹ̀bẹ̀ fún wọn; ma ṣe bẹ̀ mí, nítorí èmi kì yóò tẹ́tí sí ọ. 17Ṣé ìwọ kò rí ohun tí wọ́n ń ṣe ní àwọn ìlú Juda àti ní òpópó Jerusalẹmu? 18Àwọn ọmọ ṣa igi jọ, àwọn baba fi iná sí i, àwọn ìyá sì po ìyẹ̀fun láti ṣe àkàrà fún ayaba ọ̀run, wọ́n tú ẹbọ ọrẹ mímu sí àwọn ọlọ́run àjèjì láti ru bínú mi sókè. 19Ṣùgbọ́n ṣe èmi ni wọ́n fẹ́ mú bínú? ni Olúwa wí. Ǹjẹ́ kì í ṣe pé wọ́n kúkú ń pa ara wọn lára sí ìtìjú ara wọn?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.