Jeremiah 51:23
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èmi yóò sì fi ọ́ fọ́ olùṣọ́-àgùntàn, àti agbo àgùntàn rẹ̀ túútúú, èmi yóò sì fi ọ́ fọ́ àgbẹ̀ àti àjàgà màlúù túútúú, èmi yóò sì fi ọ́ fọ́ baálẹ̀ àti àwọn ìjòyè rẹ̀ túútúú.
Jeremiah 51:23 in English
Jeremiah 51:23 · Berean Standard Bible
With you I shatter the shepherd and his flock; with you I shatter the farmer and his oxen; with you I shatter the governors and officials.
Context
21Pẹ̀lú rẹ, èmi ó pa ẹṣin àti ẹni tí ó gùn ún pẹ̀lú rẹ̀;
èmi ó ba kẹ̀kẹ́ ogun jẹ́ pẹ̀lú
èmi ó pa awakọ̀, 22pẹ̀lú rẹ, mo pa ọkùnrin àti obìnrin,
pẹ̀lú rẹ, mo pa àgbàlagbà àti ọmọdé,
pẹ̀lú rẹ, mo pa ọ̀dọ́mọkùnrin àti ọ̀dọ́mọbìnrin. 23Èmi yóò sì fi ọ́ fọ́ olùṣọ́-àgùntàn,
àti agbo àgùntàn rẹ̀ túútúú,
èmi yóò sì fi ọ́ fọ́ àgbẹ̀ àti àjàgà màlúù túútúú,
èmi yóò sì fi ọ́ fọ́ baálẹ̀ àti àwọn ìjòyè rẹ̀ túútúú. 24“Ní ojú rẹ, èmi yóò san án fún Babeli àti gbogbo àwọn olùgbé inú rẹ̀ fún gbogbo ibi tí wọ́n ti ṣe ní Sioni,”
ni Olúwa wí. 25“Mo lòdì sí ọ, ìwọ òkè apanirun
ìwọ ti ba gbogbo ayé jẹ́,”
ni Olúwa wí.
“Èmi ó na ọwọ́ mi sí ọ,
èmi yóò yí ọ kúrò lórí àpáta,
Èmi yóò sọ ọ́ dàbí òkè tí a ti jó.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.