Jeremiah 50:5
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Wọn ó máa béèrè ọ̀nà Sioni, ojú wọn yóò sì yí síhà ibẹ̀, wí pé ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a darapọ̀ mọ́ Olúwa ní májẹ̀mú ayérayé, tí a kì yóò gbàgbé.
Jeremiah 50:5 in English
Jeremiah 50:5 · Berean Standard Bible
They will ask the way to Zion and turn their faces toward it. They will come and join themselves to the LORD in an everlasting covenant that will never be forgotten.
Context
3Àwọn ìlú ní apá àríwá yóò
sì máa gbóguntì wọ́n.
Gbogbo àwọn ènìyàn àti ẹranko ni yóò
sá kúrò ní ìlú yìí. 4“Ní ọjọ́ wọ̀nyí àti ní àkókò náà,”
ni Olúwa wí,
“Àwọn ọmọ Israẹli yóò jùmọ̀ wá,
àwọn, àti àwọn ọmọ Juda,
wọn yóò lọ pẹ̀lú ẹkún láti ṣàfẹ́rí
Olúwa Ọlọ́run wọn. 5Wọn ó máa béèrè ọ̀nà Sioni,
ojú wọn yóò sì yí síhà ibẹ̀,
wí pé ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a darapọ̀ mọ́ Olúwa
ní májẹ̀mú ayérayé,
tí a kì yóò gbàgbé. 6“Àwọn ènìyàn mi ti jẹ́ àgùntàn tí ó sọnù,
àwọn olùṣọ́-àgùntàn wọn ti jẹ́ kí wọn ṣìnà,
wọ́n ti jẹ́ kí wọn rìn lórí òkè
wọ́n ti lọ láti orí òkè ńlá dé òkè kékeré,
wọn ti gbàgbé ibùsùn wọn. 7Gbogbo àwọn tí ó rí wọn, ti pa wọ́n jẹ
àwọn ọ̀tá wọ́n sì wí pé, ‘Àwa kò jẹ̀bi
nítorí pé wọ́n ti ṣẹ̀ sí Olúwa ibùgbé
òdodo àti ìrètí àwọn baba wọn.’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.