Jeremiah 48:36
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Nítorí náà ọkàn mi ró fún Moabu bí fèrè, ọkàn mi ró bí fèrè fún àwọn ọkùnrin Kiri-Hareseti. Nítorí ìṣúra tí ó kójọ ṣègbé.
Jeremiah 48:36 in English
Jeremiah 48:36 · Berean Standard Bible
Therefore My heart laments like a flute for Moab; it laments like a flute for the men of Kir-heres, because the wealth they acquired has perished.
Context
34“Ohùn igbe wọn gòkè
láti Heṣboni dé Eleale àti Jahasi,
láti Soari títí dé Horonaimu àti Eglati-Ṣeliṣi,
nítorí àwọn omi Nimrimu pẹ̀lú yóò gbẹ. 35Ní ti Moabu ni èmi yóò ti fi òpin sí
ẹni tí ó rú ẹbọ ní ibí gíga
àti ẹni tí ń sun tùràrí fún òrìṣà rẹ̀,”
ni Olúwa wí. 36“Nítorí náà ọkàn mi ró fún Moabu bí fèrè,
ọkàn mi ró bí fèrè fún àwọn ọkùnrin Kiri-Hareseti.
Nítorí ìṣúra tí ó kójọ ṣègbé. 37Gbogbo orí ni yóò pá,
gbogbo irùngbọ̀n ni a ó gé kúrò,
gbogbo ọwọ́ ni a sá lọ́gbẹ́,
àti aṣọ ọ̀fọ̀ ní gbogbo ẹ̀gbẹ́. 38Ẹkún ńlá ní yóò wà lórí gbogbo òrùlé Moabu,
àti ní ìta rẹ̀,
nítorí èmi ti fọ́ Moabu
bí a ti ń fọ́ ohun èlò tí kò wu ni,”
ni Olúwa wí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.