Jeremiah 48:16
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Ìṣubú Moabu súnmọ́; ìpọ́njú yóò dé kánkán.
Jeremiah 48:16 in English
Jeremiah 48:16 · Berean Standard Bible
Moab’s calamity is at hand, and his affliction is rushing swiftly.
Context
14“Báwo ni o ṣe lè sọ pé, ‘Ajagun ni wá,
alágbára ní ogun jíjà’? 15A ó pa Moabu run, a ó sì gba àwọn ìlú rẹ̀;
a ó sì dúńbú àwọn arẹwà ọkùnrin rẹ̀,”
ni ọba wí, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa àwọn ọmọ-ogun. 16“Ìṣubú Moabu súnmọ́;
ìpọ́njú yóò dé kánkán. 17Ẹ dárò fún, gbogbo ẹ̀yin tí ó yí i ká
gbogbo ẹ̀yin tí ẹ mọ bí ó ti ní òkìkí tó.
Ẹ sọ pé, ‘Báwo ni ọ̀pá agbára rẹ
títóbi tí ó sì lógo ṣe fọ́!’ 18“Sọ̀kalẹ̀ níbi ògo rẹ,
kí o sì jókòó ní ilẹ̀ gbígbẹ,
ẹ̀yin olùgbé ọmọbìnrin Diboni,
nítorí tí ẹni tí ó pa Moabu run
yóò dojúkọ ọ́
yóò sì pa àwọn ìlú olódi rẹ run.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.