Jeremiah 48:13
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà náà Moabu yóò sì tú u nítorí Kemoṣi, bí ojú ti í ti ilé Israẹli nígbà tí ó gbẹ́kẹ̀lé Beteli.
Jeremiah 48:13 in English
Jeremiah 48:13 · Berean Standard Bible
Then Moab will be ashamed of Chemosh, just as the house of Israel was ashamed when they trusted in Bethel.
Context
11“Moabu ti wà ní ìsinmi láti ìgbà èwe rẹ̀ wá
bí i ọtí wáìnì lórí gẹ̀dẹ̀gẹ́dẹ̀ rẹ̀,
tí a kò dà láti ìgò kan sí èkejì
kò tí ì lọ sí ilẹ̀ ìgbèkùn rí.
Ó dùn lẹ́nu bí ó ti yẹ,
òórùn rẹ̀ kò yí padà. 12Ṣùgbọ́n ọjọ́ ń bọ̀,” ni Olúwa wí,
“nígbà tí n ó rán àwọn tí ó n da ọtí láti inú àwọn ìgò
tí wọ́n ó sì dà á síta;
wọn ó sọ àwọn ìgò rẹ̀ di òfo,
wọn ó sì fọ́ àwọn ife rẹ̀. 13Nígbà náà Moabu yóò sì tú u nítorí Kemoṣi,
bí ojú ti í ti ilé Israẹli
nígbà tí ó gbẹ́kẹ̀lé Beteli. 14“Báwo ni o ṣe lè sọ pé, ‘Ajagun ni wá,
alágbára ní ogun jíjà’? 15A ó pa Moabu run, a ó sì gba àwọn ìlú rẹ̀;
a ó sì dúńbú àwọn arẹwà ọkùnrin rẹ̀,”
ni ọba wí, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Olúwa àwọn ọmọ-ogun.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.