Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣé ẹ̀yin ti gbàgbé ibi tí àwọn baba ńlá yín àti àwọn ọba; àwọn ayaba Juda, àti àwọn ibi tí ẹ ti ṣe àti àwọn ìyàwó yín ní ilẹ̀ Juda àti ní òpópó Jerusalẹmu?

Jeremiah 44:9 in English

Jeremiah 44:9 · Berean Standard Bible

Have you forgotten the wickedness of your fathers and of the kings of Judah and their wives, as well as the wickedness that you and your wives committed in the land of Judah and in the streets of Jerusalem?

Context

7“Báyìí tún ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun Israẹli wí, kí ló dé tí ẹ fi ń mu ibi ńlá yìí wá sí orí ara yín nípa yíyapa kúrò lára Juda ọkùnrin àti obìnrin, ọmọdé àti èwe, tí ẹ kò sì ku ọ̀kankan? 8Èéṣe tí ẹ fi mú mi bínú pẹ̀lú ohun tí ọwọ́ yín ṣe pẹ̀lú ẹbọ sísun sí àwọn òrìṣà Ejibiti, níbi tí ẹ wá láti máa gbé? Ẹ̀ ò pa ara yín run, ẹ̀ ó sì sọ ara yín di ẹni ìfiré àti ẹ̀gàn láàrín àwọn orílẹ̀-èdè ayé gbogbo. 9Ṣé ẹ̀yin ti gbàgbé ibi tí àwọn baba ńlá yín àti àwọn ọba; àwọn ayaba Juda, àti àwọn ibi tí ẹ ti ṣe àti àwọn ìyàwó yín ní ilẹ̀ Juda àti ní òpópó Jerusalẹmu? 10Láti ìgbà náà sí àkókò yìí, wọn kò rẹ ara wọn sílẹ̀ tàbí fi ìtẹríba hàn tàbí kí wọn ó tẹ̀lé òfin àti àṣẹ tí mo pa fún un yín àti àwọn baba yín. 11“Fún ìdí èyí, báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run àwọn Israẹli wí: Mo ti pinnu láti mú ibi wá sí orí yín àti láti pa Juda run.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.