Jeremiah 44:8
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èéṣe tí ẹ fi mú mi bínú pẹ̀lú ohun tí ọwọ́ yín ṣe pẹ̀lú ẹbọ sísun sí àwọn òrìṣà Ejibiti, níbi tí ẹ wá láti máa gbé? Ẹ̀ ò pa ara yín run, ẹ̀ ó sì sọ ara yín di ẹni ìfiré àti ẹ̀gàn láàrín àwọn orílẹ̀-èdè ayé gbogbo.
Jeremiah 44:8 in English
Jeremiah 44:8 · Berean Standard Bible
Why are you provoking Me to anger by the work of your hands by burning incense to other gods in the land of Egypt, where you have gone to reside? As a result, you will be cut off and will become an object of cursing and reproach among all the nations of the earth.
Context
6Fún ìdí èyí, ìbínú gbígbóná mi ni èmi yóò yọ sí àwọn ìlú Juda àti òpópó Jerusalẹmu àti sísọ wọ́n di ìparun bí ó ṣe wà lónìí yìí. 7“Báyìí tún ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun Israẹli wí, kí ló dé tí ẹ fi ń mu ibi ńlá yìí wá sí orí ara yín nípa yíyapa kúrò lára Juda ọkùnrin àti obìnrin, ọmọdé àti èwe, tí ẹ kò sì ku ọ̀kankan? 8Èéṣe tí ẹ fi mú mi bínú pẹ̀lú ohun tí ọwọ́ yín ṣe pẹ̀lú ẹbọ sísun sí àwọn òrìṣà Ejibiti, níbi tí ẹ wá láti máa gbé? Ẹ̀ ò pa ara yín run, ẹ̀ ó sì sọ ara yín di ẹni ìfiré àti ẹ̀gàn láàrín àwọn orílẹ̀-èdè ayé gbogbo. 9Ṣé ẹ̀yin ti gbàgbé ibi tí àwọn baba ńlá yín àti àwọn ọba; àwọn ayaba Juda, àti àwọn ibi tí ẹ ti ṣe àti àwọn ìyàwó yín ní ilẹ̀ Juda àti ní òpópó Jerusalẹmu? 10Láti ìgbà náà sí àkókò yìí, wọn kò rẹ ara wọn sílẹ̀ tàbí fi ìtẹríba hàn tàbí kí wọn ó tẹ̀lé òfin àti àṣẹ tí mo pa fún un yín àti àwọn baba yín.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.