Jeremiah 44:25
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí. Ìwọ àti àwọn ìyàwó rẹ fihàn pẹ̀lú àwọn ìhùwà rẹ àti àwọn ohun tí ó ṣèlérí nígbà tí o wí pé, ‘Àwa yóò mú ẹ̀jẹ́ tí a jẹ́ ṣẹ lórí sísun tùràrí àti dída ẹbọ ohun mímu sí orí ère Ayaba Ọ̀run.’ “Tẹ̀síwájú nígbà náà, ṣe ohun tí o sọ, kí o sì mú ẹ̀jẹ́ rẹ ṣẹ.
Jeremiah 44:25 in English
Jeremiah 44:25 · Berean Standard Bible
This is what the LORD of Hosts, the God of Israel, says: As for you and your wives, you have spoken with your mouths and fulfilled with your hands your words: ‘We will surely perform our vows that we have made to burn incense to the Queen of Heaven and to pour out drink offerings to her.’ Go ahead, then, do what you have promised! Keep your vows!
Context
23Nítorí pé ẹ ti sun ẹbọ, tí ẹ sì ti ṣẹ̀ sí Olúwa àti pé ẹ kò gbọ́rọ̀ sí i lẹ́nu, àti pé ẹ kò sì tẹ̀lé òfin rẹ̀ àti àwọn àṣẹ. Ibi náà yóò wá sórí rẹ àti bí o ṣe rí i.” 24Nígbà náà ni Jeremiah dáhùn pẹ̀lú obìnrin náà pé, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin ọmọ Juda tí ó wà ní Ejibiti. 25Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí. Ìwọ àti àwọn ìyàwó rẹ fihàn pẹ̀lú àwọn ìhùwà rẹ àti àwọn ohun tí ó ṣèlérí nígbà tí o wí pé, ‘Àwa yóò mú ẹ̀jẹ́ tí a jẹ́ ṣẹ lórí sísun tùràrí àti dída ẹbọ ohun mímu sí orí ère Ayaba Ọ̀run.’
“Tẹ̀síwájú nígbà náà, ṣe ohun tí o sọ, kí o sì mú ẹ̀jẹ́ rẹ ṣẹ. 26Ṣùgbọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa Olódùmarè, gbogbo ẹ̀yin Júù tí ń gbé ilẹ̀ Ejibiti, mo gégùn ún: ‘Mo búra pẹ̀lú títóbi orúkọ mi,’ bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wí, ‘pé kò sí ẹnikẹ́ni láti Juda tí ń gbé ibikíbi ní Ejibiti tí ó gbọdọ̀ ké pe orúkọ mi tàbí búra, “Gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run tí ó dá wa ti wà láààyè.” 27Nítorí náà, èmi ó ṣọ wọ́n fún ibi, kì í ṣe fún rere. Àti gbogbo àwọn ọkùnrin Juda tí ó wà ní ilẹ̀ Ejibiti ni a ó parun pẹ̀lú idà àti ìyàn títí tí gbogbo wọn yóò fi tán.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.