Jeremiah 42:17
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nítorí náà, gbogbo àwọn tí ó ti pinnu láti ṣe àtìpó ní Ejibiti ni yóò ti ipa idà kú, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn kò sì ní jẹ́ kí ẹnikẹ́ni nínú wọn yè tàbí sá àsálà nínú ibi tí èmi yóò mú wá sórí wọn.’
Jeremiah 42:17 in English
Jeremiah 42:17 · Berean Standard Bible
So all who resolve to go to Egypt to reside there will die by sword and famine and plague. Not one of them will survive or escape the disaster I will bring upon them.’
Context
15nítorí náà, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin ìyókù Juda èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun Israẹli wí: ‘Bí ẹ̀yin bá pinnu láti lọ sí Ejibiti láti lọ ṣe àtìpó níbẹ̀. 16Yóò sì ṣe, idà tí ẹ̀yin bẹ̀rù yóò sì lé e yín bá níbẹ̀; àti ìyanu náà tí ẹ̀yin ń bẹ̀rù yóò sì tẹ̀lé yín lọ sí Ejibiti àti pé ibẹ̀ ni ẹ̀yin yóò kú sí. 17Nítorí náà, gbogbo àwọn tí ó ti pinnu láti ṣe àtìpó ní Ejibiti ni yóò ti ipa idà kú, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn kò sì ní jẹ́ kí ẹnikẹ́ni nínú wọn yè tàbí sá àsálà nínú ibi tí èmi yóò mú wá sórí wọn.’ 18Báyìí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí: ‘Gẹ́gẹ́ bí èmi ti da ìbínú àti ìrunú síta sórí àwọn tí ó ń gbé ní Jerusalẹmu, bẹ́ẹ̀ ni ìrunú mi yóò dà síta sórí yín, nígbà tí ẹ̀yin bá lọ sí Ejibiti. Ẹ̀yin ó sì di ẹni ègún àti ẹni ẹ̀gàn àti ẹ̀sín, ẹ̀yin kì yóò sì rí ibí yìí mọ́.’ 19“Ẹ̀yin yòókù Juda, Olúwa ti sọ fún un yín pé, ‘Kí ẹ má ṣe lọ sí Ejibiti.’ Ẹ mọ èyí dájú, èmi kìlọ̀ fún un yín lónìí,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.