Jeremiah 42:15
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
nítorí náà, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin ìyókù Juda èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun Israẹli wí: ‘Bí ẹ̀yin bá pinnu láti lọ sí Ejibiti láti lọ ṣe àtìpó níbẹ̀.
Jeremiah 42:15 in English
Jeremiah 42:15 · Berean Standard Bible
then hear the word of the LORD, O remnant of Judah! This is what the LORD of Hosts, the God of Israel, says: ‘If you are determined to go to Egypt and reside there,
Context
13“Ṣùgbọ́n sá, bí ẹ̀yin bá wí pé, ‘Àwa kò ní gbé ilẹ̀ yìí,’ ẹ̀yin ti ṣe àìgbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run yín. 14Àti pé bí ẹ̀yin bá wí pé, ‘Bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa yóò lọ gbé ní Ejibiti; níbi tí àwa kì yóò rí ìró ogunkógun, tí a kì yóò sì gbọ́ ìró fèrè, tí ebi oúnjẹ kì yóò sì pa wá, níbẹ̀ ni àwa ó sì máa gbé,’ 15nítorí náà, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin ìyókù Juda èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun Israẹli wí: ‘Bí ẹ̀yin bá pinnu láti lọ sí Ejibiti láti lọ ṣe àtìpó níbẹ̀. 16Yóò sì ṣe, idà tí ẹ̀yin bẹ̀rù yóò sì lé e yín bá níbẹ̀; àti ìyanu náà tí ẹ̀yin ń bẹ̀rù yóò sì tẹ̀lé yín lọ sí Ejibiti àti pé ibẹ̀ ni ẹ̀yin yóò kú sí. 17Nítorí náà, gbogbo àwọn tí ó ti pinnu láti ṣe àtìpó ní Ejibiti ni yóò ti ipa idà kú, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn kò sì ní jẹ́ kí ẹnikẹ́ni nínú wọn yè tàbí sá àsálà nínú ibi tí èmi yóò mú wá sórí wọn.’
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.