Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ọmọ-ogun Babeli lé wọn, wọ́n bá Sedekiah láàrín aginjù Jeriko. Wọ́n mú un ní ìgbèkùn, wọ́n sì mú u tọ Nebukadnessari ọba Babeli àti Ribla ní ilẹ̀ Hamati, níbi tí wọ́n ti ṣe ìdájọ́ rẹ̀.

Jeremiah 39:5 in English

Jeremiah 39:5 · Berean Standard Bible

But the army of the Chaldeans * pursued them and overtook Zedekiah in the plains of Jericho. They seized him and brought him up to Nebuchadnezzar king of Babylon at Riblah in the land of Hamath, where he pronounced judgment on him.

Context

3Nígbà náà ni gbogbo àwọn ìjòyè ọba Babeli wá, wọ́n sì jókòó ní àárín ẹnu ibodè, àní Nergali-Ṣareseri ti Samgari, Nebo-Sarsikimu olórí ìwẹ̀fà, Nergali-Ṣareseri, olórí amòye, pẹ̀lú gbogbo àwọn ìjòyè ọba Babeli yóò kú. 4Nígbà tí Sedekiah ọba Juda àti àwọn ọmọ-ogun rí wọn, wọ́n sá, wọ́n kúrò ní ìlú ní alẹ́, wọ́n gba ọ̀nà ọgbà ọba lọ láàrín ẹnu ibodè pẹ̀lú odi méjì, wọ́n dojúkọ aginjù. 5Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ọmọ-ogun Babeli lé wọn, wọ́n bá Sedekiah láàrín aginjù Jeriko. Wọ́n mú un ní ìgbèkùn, wọ́n sì mú u tọ Nebukadnessari ọba Babeli àti Ribla ní ilẹ̀ Hamati, níbi tí wọ́n ti ṣe ìdájọ́ rẹ̀. 6Níbẹ̀ ní Ribla, ni ọba Babeli ti dúńbú àwọn ọmọ Sedekiah lójú rẹ̀, tí ó sì tún pa gbogbo àwọn ọlọ́lá ilẹ̀ Juda. 7Nígbà náà ni ó fọ́ ojú Sedekiah, ó sì dè é pẹ̀lú ẹ̀wọ̀n láti gbé e lọ sí ilẹ̀ Babeli.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.