Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ebedimeleki jáde kúrò láàfin ọba, ó sì sọ fún un pé,

Jeremiah 38:8 in English

Jeremiah 38:8 · Berean Standard Bible

Ebed-melech went out from the king’s palace and said to the king,

Context

6Wọ́n gbé Jeremiah sọ sínú ihò Malkiah, ọmọ ọba, tí ó wà ní àgbàlá ilé túbú; wọ́n fi okùn sọ Jeremiah kalẹ̀ sí ìsàlẹ̀ ihò; kò sì ṣí omi nínú ihò náà bí kò ṣe ẹrọ̀fọ̀, Jeremiah sì rì sínú ẹrọ̀fọ̀ náà. 7Ṣùgbọ́n, Ebedimeleki, ará Kuṣi ìjòyè nínú ààfin ọba gbọ́ pé wọ́n ti ju Jeremiah sínú kànga. Nígbà tí ọba jókòó ní ẹnu-bodè Benjamini. 8Ebedimeleki jáde kúrò láàfin ọba, ó sì sọ fún un pé, 9“Olúwa mi ọba, àwọn ènìyàn wọ̀nyí ti ṣe ohun búburú sí Jeremiah wòlíì Ọlọ́run. Wọ́n ti gbé e sọ sínú kànga níbi tí kò sí oúnjẹ kankan nínú ìlú mọ́.” 10Nígbà náà ni ọba pàṣẹ fún Ebedimeleki ará Kuṣi pé, “Mú ọgbọ̀n ọkùnrin láti ibí pẹ̀lú rẹ, kí ẹ sì fa wòlíì Jeremiah sókè láti inú ihò, kí ó tó kú.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.