Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n, Ebedimeleki, ará Kuṣi ìjòyè nínú ààfin ọba gbọ́ pé wọ́n ti ju Jeremiah sínú kànga. Nígbà tí ọba jókòó ní ẹnu-bodè Benjamini.

Jeremiah 38:7 in English

Jeremiah 38:7 · Berean Standard Bible

Now Ebed-melech the Cushite,* a court official * in the royal palace, heard that Jeremiah had been put into the cistern. While the king was sitting at the Gate of Benjamin,

Context

5Sedekiah ọba sì wí pé, “Ó wà lọ́wọ́ yín. Ọba kò lè ṣe ohunkóhun láti takò yín.” 6Wọ́n gbé Jeremiah sọ sínú ihò Malkiah, ọmọ ọba, tí ó wà ní àgbàlá ilé túbú; wọ́n fi okùn sọ Jeremiah kalẹ̀ sí ìsàlẹ̀ ihò; kò sì ṣí omi nínú ihò náà bí kò ṣe ẹrọ̀fọ̀, Jeremiah sì rì sínú ẹrọ̀fọ̀ náà. 7Ṣùgbọ́n, Ebedimeleki, ará Kuṣi ìjòyè nínú ààfin ọba gbọ́ pé wọ́n ti ju Jeremiah sínú kànga. Nígbà tí ọba jókòó ní ẹnu-bodè Benjamini. 8Ebedimeleki jáde kúrò láàfin ọba, ó sì sọ fún un pé, 9“Olúwa mi ọba, àwọn ènìyàn wọ̀nyí ti ṣe ohun búburú sí Jeremiah wòlíì Ọlọ́run. Wọ́n ti gbé e sọ sínú kànga níbi tí kò sí oúnjẹ kankan nínú ìlú mọ́.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.