Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ebedimeleki ará Kuṣi sọ fún Jeremiah pé, “Fi àkísà àti okùn bọ abẹ́ abíyá rẹ, Jeremiah sì ṣe bẹ́ẹ̀.”

Jeremiah 38:12 in English

Jeremiah 38:12 · Berean Standard Bible

Ebed-melech the Cushite cried out to Jeremiah, “Put these worn-out rags and clothes under your arms to pad the ropes.” Jeremiah did so,

Context

10Nígbà náà ni ọba pàṣẹ fún Ebedimeleki ará Kuṣi pé, “Mú ọgbọ̀n ọkùnrin láti ibí pẹ̀lú rẹ, kí ẹ sì fa wòlíì Jeremiah sókè láti inú ihò, kí ó tó kú.” 11Ebedimeleki kó àwọn ọkùnrin náà pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n lọ sínú yàrá kan nínú ààfin ọba. Ó mú àwọn aṣọ àkísà àti okùn tọ Jeremiah lọ nínú kànga. 12Ebedimeleki ará Kuṣi sọ fún Jeremiah pé, “Fi àkísà àti okùn bọ abẹ́ abíyá rẹ, Jeremiah sì ṣe bẹ́ẹ̀.” 13Báyìí ni wọ́n ṣe fi okùn yọ Jeremiah jáde, wọ́n sì mu un gòkè láti inú ihò wá, Jeremiah sì wà ní àgbàlá ilé túbú. 14Nígbà náà ni ọba Sedekiah ránṣẹ́ pe, Jeremiah òjíṣẹ́ Ọlọ́run àti láti mú un wá sí ẹnu ibodè kẹta nílé Olúwa. Ọba sì sọ fún Jeremiah pé, “Èmi yóò bi ọ́ ní ohun kan; má sì ṣe fi ohun kan pamọ́ fún mi.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.