Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Baruku ọmọ Neriah sì ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí wòlíì Jeremiah sọ fún, láti ka ọ̀rọ̀ Olúwa láti inú ìwé ní ilé Olúwa.

Jeremiah 36:8 in English

Jeremiah 36:8 · Berean Standard Bible

So Baruch son of Neriah did everything that Jeremiah the prophet had commanded him. In the house of the LORD he read the words of the LORD from the scroll.

Context

6Nítorí náà, ìwọ lọ sí ilé Olúwa ní ọjọ́ àwẹ̀, kí o sì kà nínú ìwé kíká náà ọ̀rọ̀ Olúwa tí ìwọ ti ẹnu mi kọ; ìwọ ó sì kà á ní etí gbogbo Juda, tí wọ́n jáde wá láti ìlú wọn. 7Ó lè jẹ́ pé, ẹ̀bẹ̀ wọn yóò wá sí iwájú Olúwa, wọ́n ó sì yípadà kúrò ní ọ̀nà búburú wọn; nítorí pé títóbi ni ìbínú àti ìrunú tí Olúwa ti sọ sí àwọn ènìyàn yìí.” 8Baruku ọmọ Neriah sì ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí wòlíì Jeremiah sọ fún, láti ka ọ̀rọ̀ Olúwa láti inú ìwé ní ilé Olúwa. 9Ní oṣù kẹsànán ọdún karùn-ún Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda ni wọ́n kéde àwẹ̀ níwájú Olúwa fún gbogbo ènìyàn Jerusalẹmu àti fún gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wá láti ìlú Juda. 10Láti inú yàrá Gemariah ọmọ Ṣafani akọ̀wé, ní àgbàlá òkè níbi ìlẹ̀kùn ẹnu-ọ̀nà ilé Olúwa tuntun. Baruku sì ka ọ̀rọ̀ Jeremiah láti inú ìwé ní ilé Olúwa sí etí gbogbo ènìyàn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.