Native Bible

Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó lè jẹ́ pé, ẹ̀bẹ̀ wọn yóò wá sí iwájú Olúwa, wọ́n ó sì yípadà kúrò ní ọ̀nà búburú wọn; nítorí pé títóbi ni ìbínú àti ìrunú tí Olúwa ti sọ sí àwọn ènìyàn yìí.”

Jeremiah 36:7 in English

Jeremiah 36:7 · Berean Standard Bible

Perhaps they will bring their petition before the LORD, and each one will turn from his wicked way; for great are the anger and fury that the LORD has pronounced against this people.”

Context

5Nígbà náà ni Jeremiah wí fún Baruku pé, “A sé mi mọ́! Èmi kò lè lọ sí ilé Olúwa. 6Nítorí náà, ìwọ lọ sí ilé Olúwa ní ọjọ́ àwẹ̀, kí o sì kà nínú ìwé kíká náà ọ̀rọ̀ Olúwa tí ìwọ ti ẹnu mi kọ; ìwọ ó sì kà á ní etí gbogbo Juda, tí wọ́n jáde wá láti ìlú wọn. 7Ó lè jẹ́ pé, ẹ̀bẹ̀ wọn yóò wá sí iwájú Olúwa, wọ́n ó sì yípadà kúrò ní ọ̀nà búburú wọn; nítorí pé títóbi ni ìbínú àti ìrunú tí Olúwa ti sọ sí àwọn ènìyàn yìí.” 8Baruku ọmọ Neriah sì ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí tí wòlíì Jeremiah sọ fún, láti ka ọ̀rọ̀ Olúwa láti inú ìwé ní ilé Olúwa. 9Ní oṣù kẹsànán ọdún karùn-ún Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda ni wọ́n kéde àwẹ̀ níwájú Olúwa fún gbogbo ènìyàn Jerusalẹmu àti fún gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wá láti ìlú Juda.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.