Jeremiah 35:2
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Lọ sí ilé àwọn ọmọ Rekabu, kí o sì bá wọn sọ̀rọ̀, kí o sì mú wọn wá sí ilé Olúwa, sí ọ̀kan nínú iyàrá wọ̀n-ọn-nì, kí o sì fún wọn ní ọtí wáìnì mu.”
Jeremiah 35:2 in English
Jeremiah 35:2 · Berean Standard Bible
“Go to the house of the Rechabites, speak to them, and bring them to one of the chambers of the house of the LORD to offer them a drink of wine.”
Context
1Ọ̀rọ̀ tí ó tọ Jeremiah wá láti ọ̀dọ̀ Olúwa ní ọjọ́ Jehoiakimu ọmọ Josiah ọba Juda wí pé: 2“Lọ sí ilé àwọn ọmọ Rekabu, kí o sì bá wọn sọ̀rọ̀, kí o sì mú wọn wá sí ilé Olúwa, sí ọ̀kan nínú iyàrá wọ̀n-ọn-nì, kí o sì fún wọn ní ọtí wáìnì mu.” 3Nígbà náà ni mo mu Jaaṣaniah ọmọ Jeremiah, ọmọ Habasiniah àti àwọn arákùnrin rẹ̀; àti gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀, àti gbogbo ilé àwọn ọmọ Rekabu. 4Mo sì mú wọn wá sí ilé Olúwa sínú iyàrá Hanani ọmọ Igdaliah, ènìyàn Ọlọ́run, tí ó wà lẹ́bàá yàrá àwọn ìjòyè, tí ó wà ní òkè yàrá Maaseiah, ọmọ Ṣallumu olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.