Jeremiah 34:4
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“ ‘Síbẹ̀, gbọ́ ìlérí Olúwa, ìwọ Sedekiah ọba Juda. Èyí ni ohun tí Ọlọ́run wí nípa rẹ; ìwọ kì yóò ti ipa idà kú;
Jeremiah 34:4 in English
Jeremiah 34:4 · Berean Standard Bible
Yet hear the word of the LORD, O Zedekiah king of Judah. This is what the LORD says concerning you: You will not die by the sword;
Context
2“Èyí ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run Israẹli ọmọ-ogun wí: Lọ sí ọ̀dọ̀ Sedekiah ọba Juda kí o sì sọ fún un pé, ‘Èyí ni ohun tí Ọlọ́run wí: Èmi fẹ́ fa ìlú yìí lé ọba Babeli lọ́wọ́, yóò sì jó palẹ̀. 3Ìwọ kò ní sá àsálà, ṣùgbọ́n à ó mú ọ, bẹ́ẹ̀ ni a ó sì fà ọ́ lé e lọ́wọ́. Ìwọ yóò rí ọba Babeli pẹ̀lú ojú ara rẹ; yóò sì bá ọ sọ̀rọ̀ lójúkojú; ìwọ yóò sì lọ sí Babeli. 4“ ‘Síbẹ̀, gbọ́ ìlérí Olúwa, ìwọ Sedekiah ọba Juda. Èyí ni ohun tí Ọlọ́run wí nípa rẹ; ìwọ kì yóò ti ipa idà kú; 5ìwọ yóò kú ní àlàáfíà. Bí àwọn ènìyàn sì ti ń ṣe iná ìsìnkú ní ọlá fún àwọn baba rẹ, ọba tí ó jẹ ṣáájú rẹ, bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò ṣe iná ní ọlá rẹ, wọn ó sì pohùnréré pé, “Yé, olúwa!” Èmi fúnra mi ni ó ṣèlérí yìí ni Olúwa wí.’ ” 6Nígbà náà ni Jeremiah wòlíì sọ gbogbo nǹkan yìí fún Sedekiah ọba Juda ní Jerusalẹmu.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.