Jeremiah 32:31
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Láti ọjọ́ tí wọ́n ti kọ́ ọ, títí di àkókò yìí ni ìlú yìí ti jẹ́ ohun ìbínú àti ìyọnu fún mi tó bẹ́ẹ̀ tí èmi yóò fà á tu kúrò níwájú mi.
Jeremiah 32:31 in English
Jeremiah 32:31 · Berean Standard Bible
For this city has aroused My wrath and fury from the day it was built until now. Therefore I will remove it from My presence
Context
29Àwọn ará Kaldea tí ó ń gbógun tí ìlú yóò wọ ìlú. Wọn ó sì fi iná sí ìlú; wọn ó jó o palẹ̀ pẹ̀lú ilé tí àwọn ènìyàn ti ń mú mi bínú, tí wọ́n ń rú ẹbọ tùràrí lórí pẹpẹ fún Baali tiwọn sì ń da ẹbọ ohun mímu fún àwọn ọlọ́run mìíràn. 30“Àwọn ènìyàn Israẹli àti Juda kò ṣe ohun kankan bí kò ṣe ibi lójú mi láti ìgbà èwe wọn. Nítorí àwọn ọmọ Israẹli ti fi kìkì iṣẹ́ ọwọ́ wọ́n mú mi bínú ni Olúwa wí. 31Láti ọjọ́ tí wọ́n ti kọ́ ọ, títí di àkókò yìí ni ìlú yìí ti jẹ́ ohun ìbínú àti ìyọnu fún mi tó bẹ́ẹ̀ tí èmi yóò fà á tu kúrò níwájú mi. 32Àwọn ènìyàn Israẹli àti àwọn ènìyàn Juda ti mú mi bínú pẹ̀lú gbogbo ìbàjẹ́ tí wọ́n ṣe. Àwọn Israẹli, ọba wọn àti gbogbo ìjòyè, àlùfáà àti wòlíì, àwọn ọkùnrin Juda àti àwọn ènìyàn Jerusalẹmu. 33Wọ́n kọ ẹ̀yìn sí mi, wọ́n sì yí ojú wọn padà. Èmi kọ wọ́n, síbẹ̀ wọn kò fetísílẹ̀ láti gbọ́ ẹ̀kọ́ tàbí kọbi ara sí ìwà ìbàjẹ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.