Jeremiah 32:30
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Àwọn ènìyàn Israẹli àti Juda kò ṣe ohun kankan bí kò ṣe ibi lójú mi láti ìgbà èwe wọn. Nítorí àwọn ọmọ Israẹli ti fi kìkì iṣẹ́ ọwọ́ wọ́n mú mi bínú ni Olúwa wí.
Jeremiah 32:30 in English
Jeremiah 32:30 · Berean Standard Bible
For the children of Israel and of Judah have done nothing but evil in My sight from their youth; indeed, they have done nothing but provoke Me to anger by the work of their hands, declares the LORD.
Context
28Nítorí náà, báyìí ni Olúwa wí, Èmi ṣetán láti fi ìlú yìí fún àwọn ará Kaldea àti fún Nebukadnessari ọba Babeli ẹni tí yóò kó o. 29Àwọn ará Kaldea tí ó ń gbógun tí ìlú yóò wọ ìlú. Wọn ó sì fi iná sí ìlú; wọn ó jó o palẹ̀ pẹ̀lú ilé tí àwọn ènìyàn ti ń mú mi bínú, tí wọ́n ń rú ẹbọ tùràrí lórí pẹpẹ fún Baali tiwọn sì ń da ẹbọ ohun mímu fún àwọn ọlọ́run mìíràn. 30“Àwọn ènìyàn Israẹli àti Juda kò ṣe ohun kankan bí kò ṣe ibi lójú mi láti ìgbà èwe wọn. Nítorí àwọn ọmọ Israẹli ti fi kìkì iṣẹ́ ọwọ́ wọ́n mú mi bínú ni Olúwa wí. 31Láti ọjọ́ tí wọ́n ti kọ́ ọ, títí di àkókò yìí ni ìlú yìí ti jẹ́ ohun ìbínú àti ìyọnu fún mi tó bẹ́ẹ̀ tí èmi yóò fà á tu kúrò níwájú mi. 32Àwọn ènìyàn Israẹli àti àwọn ènìyàn Juda ti mú mi bínú pẹ̀lú gbogbo ìbàjẹ́ tí wọ́n ṣe. Àwọn Israẹli, ọba wọn àti gbogbo ìjòyè, àlùfáà àti wòlíì, àwọn ọkùnrin Juda àti àwọn ènìyàn Jerusalẹmu.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.