Jeremiah 31:35
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Èyí ni ohun tí Olúwa wí: ẹni tí ó mú oòrùn tan ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀sán, tí ó mú òṣùpá àti ìràwọ̀ ràn ní òru; tí ó rú omi Òkun sókè tó bẹ́ẹ̀ tí ìjì rẹ̀ fi ń hó Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀.
Jeremiah 31:35 in English
Jeremiah 31:35 · Berean Standard Bible
Thus says the LORD, who gives the sun for light by day, who sets in order the moon and stars for light by night, who stirs up the sea so that its waves roar—the LORD of Hosts is His name:
Context
33“Èyí ni májẹ̀mú tí èmi yóò bá ilé Israẹli dá
lẹ́yìn ìgbà náà,” ni Olúwa wí pé:
“Èmi yóò fi òfin mi sí ọkàn wọn,
èmi ó sì kọ ọ́ sí àyà wọn.
Èmi ó jẹ́ Olúwa wọn;
àwọn ó sì jẹ́ ènìyàn mi. 34Kò ní sí pé ọkùnrin kan ń kọ́ àwọn ará ilé rẹ̀
tàbí ọkùnrin ń kọ́ arákùnrin rẹ̀ pé, ‘Ẹ mọ Olúwa,’
nítorí gbogbo wọn ni yóò mọ̀ mí
láti ẹni kékeré wọn títí dé ẹni ńlá,”
ni Olúwa wí.
“Nítorí èmi ó dárí àìṣedéédéé wọn jì,
èmi kò sì ní rántí ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́.” 35Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
ẹni tí ó mú oòrùn
tan ìmọ́lẹ̀ ní ọ̀sán,
tí ó mú òṣùpá àti ìràwọ̀
ràn ní òru;
tí ó rú omi Òkun sókè
tó bẹ́ẹ̀ tí ìjì rẹ̀ fi ń hó
Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀. 36“Àyàfi tí ìlànà yìí bá kúrò níwájú mi,”
ni Olúwa wí.
“Ǹjẹ́ àwọn ọmọ Israẹli yóò dẹ́kun
láti jẹ́ orílẹ̀-èdè níwájú mi láéláé.” 37Èyí ni ohun tí Olúwa wí:
“Àyàfi tí a bá lé àwọn ọ̀run lókè
tí ìpìlẹ̀ ayé sì di àwárí ní ìsàlẹ̀,
ni èmi yóò kọ àwọn Israẹli
nítorí ohun gbogbo tí wọ́n ti ṣe,”
ni Olúwa wí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.