Jeremiah 30:21
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ọ̀kan nínú wọn ni yóò jẹ́ olórí wọn, ọba wọn yóò dìde láti àárín wọn. Èmi yóò mú un wá sí ọ̀dọ̀ mi, òun yóò sì súnmọ́ mi, nítorí ta ni ẹni náà tí yóò fi ara rẹ̀ jì láti súnmọ́ mi?’ ni Olúwa wí.
Jeremiah 30:21 in English
Jeremiah 30:21 · Berean Standard Bible
Their leader will be one of their own, and their ruler will arise from their midst. And I will bring him near, and he will approach Me, for who would dare on his own to approach Me?” declares the LORD.
Context
19Láti ẹnu wọn ni orin ọpẹ́ àti
ìyìn yóò sì ti máa jáde.
Èmi yóò sọ wọ́n di púpọ̀,
wọn kì yóò sì dínkù ní iye,
Èmi yóò fi ọlá fún wọn,
wọn kò sì ní di ẹni àbùkù. 20Ọmọ ọmọ wọn yóò wà bí i ti ìgbàanì
níwájú mi ni wọn yóò sì tẹ àwùjọ wọn dúró sí.
Gbogbo ẹni tó bá ni wọ́n lára,
ni èmi yóò fì ìyà jẹ. 21Ọ̀kan nínú wọn ni yóò jẹ́ olórí wọn,
ọba wọn yóò dìde láti àárín wọn.
Èmi yóò mú un wá sí ọ̀dọ̀ mi, òun yóò sì súnmọ́ mi,
nítorí ta ni ẹni náà tí yóò fi ara rẹ̀ jì láti súnmọ́ mi?’
ni Olúwa wí. 22‘Nítorí náà, ẹ̀yin yóò jẹ́ ènìyàn mi,
èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run yín.’ ” 23Wò ó, ìbínú Olúwa yóò tú jáde,
ìjì líle yóò sì sọ̀kalẹ̀ sórí àwọn ènìyàn búburú.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.