Jeremiah 3:25
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Jẹ́ kí a dùbúlẹ̀ nínú ìtìjú wa, kí ìtìjú wa bò wá mọ́lẹ̀. A ti ṣẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wa, àwa àti àwọn baba wa, láti ìgbà èwe wa títí di òní a kò gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wa.”
Jeremiah 3:25 in English
Jeremiah 3:25 · Berean Standard Bible
Let us lie down in our shame; let our disgrace cover us. We have sinned against the LORD our God, both we and our fathers; from our youth even to this day we have not obeyed the voice of the LORD our God.”
Context
23Nítòótọ́, asán ni ìbọ̀rìṣà àti ìrúkèrúdò tí ó wà ní àwọn orí òkè
kéékèèké àti àwọn òkè gíga,
nítòótọ́, nínú Olúwa Ọlọ́run
wa ni ìgbàlà Israẹli wà. 24Láti ìgbà èwe wa ni àwọn òrìṣà ìtìjú ti
jẹ èso iṣẹ́ àwọn baba wa run,
ọ̀wọ́ ẹran wọn àti agbo ẹran wọn,
ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn. 25Jẹ́ kí a dùbúlẹ̀ nínú ìtìjú wa,
kí ìtìjú wa bò wá mọ́lẹ̀.
A ti ṣẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wa,
àwa àti àwọn baba wa,
láti ìgbà èwe wa títí di òní
a kò gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run wa.”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.