Jeremiah 3:22
Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Padà, ẹ̀yin ènìyàn aláìnígbàgbọ́, Èmi ó wo ìpadàsẹ́yìn kúrò ní ọ̀nà títọ́ rẹ sàn.” “Bẹ́ẹ̀, ni a ó wá sọ́dọ̀ rẹ nítorí ìwọ ni Olúwa Ọlọ́run wa.
Jeremiah 3:22 in English
Jeremiah 3:22 · Berean Standard Bible
“Return, O faithless children, and I will heal your faithlessness.” “Here we are. We come to You, for You are the LORD our God.
Context
20Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí aláìgbàgbọ́ obìnrin sí ọkọ rẹ̀,
bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ o jẹ́ aláìgbàgbọ́ sí mi. Ìwọ ilé Israẹli,”
ni Olúwa wí. 21A gbọ́ ohùn àgàn láti ibi gíga,
ẹkún àti ẹ̀bẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli,
nítorí wọ́n ti yí ọ̀nà wọn po,
wọ́n sì ti gbàgbé Olúwa Ọlọ́run wọn. 22“Padà, ẹ̀yin ènìyàn aláìnígbàgbọ́,
Èmi ó wo ìpadàsẹ́yìn kúrò ní ọ̀nà títọ́ rẹ sàn.”
“Bẹ́ẹ̀, ni a ó wá sọ́dọ̀ rẹ
nítorí ìwọ ni Olúwa Ọlọ́run wa. 23Nítòótọ́, asán ni ìbọ̀rìṣà àti ìrúkèrúdò tí ó wà ní àwọn orí òkè
kéékèèké àti àwọn òkè gíga,
nítòótọ́, nínú Olúwa Ọlọ́run
wa ni ìgbàlà Israẹli wà. 24Láti ìgbà èwe wa ni àwọn òrìṣà ìtìjú ti
jẹ èso iṣẹ́ àwọn baba wa run,
ọ̀wọ́ ẹran wọn àti agbo ẹran wọn,
ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.